Suratu Al-Baqarah, aaya 180

2:180

كُتِبَ عَلَيۡكُمۡ إِذَا حَضَرَ أَحَدَكُمُ ٱلۡمَوۡتُ إِن تَرَكَ خَيۡرًا ٱلۡوَصِيَّةُ لِلۡوَٰلِدَيۡنِ وَٱلۡأَقۡرَبِينَ بِٱلۡمَعۡرُوفِۖ حَقًّا عَلَى ٱلۡمُتَّقِينَ ١٨٠

Kutiba 'alaykum idhā hadara ahadakumul-mawtu in taraka khayranil-wasiyyatu lil-wālidayni wal-aqrabīna bil-ma'rūfi haqqan 'alal-muttaqīn

A ṣe é ní ọ̀ran-anyàn fún yín, nígbà tí (àwọn àmì) ikú1 bá dé bá ẹnì kan nínú yín, tí ó sì máa fi dúkìá sílẹ̀, pé kí ó sọ àsọọ́lẹ̀2 ní ọ̀nà tó dára fún àwọn òbí méjèèjì àti àwọn ẹbí. (Èyí jẹ́) ojúṣe fún àwọn olùbẹ̀rù (Allāhu).

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Àwọn àmì ikú ni kí ẹ̀dá lérò pé ó ṣeé ṣe kí àìsàn kan tàbí ìrìn-àjò kan yọrí sí ikú fún òun. [2] Ìyẹn ni pé, kí onídúkìá fúnra rẹ̀ pín ogún rẹ̀ fún àwọn ẹbí rẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn , àwọn āyah mìíràn sọ̀kalẹ̀ tí ó pa ìdájọ́ yìí rẹ́. Àwọn āyah náà ni āyah tí Allāhu fúnra Rẹ̀ fi pín ogún òkú sūrah an-Nisā’; 7-14.