Suratu Al-Baqarah, aaya 106

2:106

۞ مَا نَنسَخۡ مِنۡ ءَايَةٍ أَوۡ نُنسِهَا نَأۡتِ بِخَيۡرٖ مِّنۡهَآ أَوۡ مِثۡلِهَآۗ أَلَمۡ تَعۡلَمۡ أَنَّ ٱللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيۡءٖ قَدِيرٌ ١٠٦

Mā nansakh min āyatin aw nunsihā na'ti bikhayrim minhā aw mithlihā alam ta'lam annallāha 'alā kulli shay'in qadīr

Ohunkóhun tí A bá parẹ́ (tàbí pààrọ̀) nínú āyah kan1 tàbí tí A sọ di ìgbàgbé, A máa mú èyí tó dára jù ú lọ tàbí irú rẹ̀ wá. Ṣé ìwọ kò mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Alágbára lórí gbogbo n̄ǹkan?

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Èyí ni pé, kí ìdájọ́ tí ó wà nínú āyah kan di ohun tí a ò níí lò mọ́ nítorí ìdájọ́ titun tí āyah mìíràn mú wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn āyah ìdájọ́ kan tí ó sọ̀kalẹ̀ lẹ́yìn Hijrah (āyah Mọdaniyyah) ṣe pa ìdájọ́ àwọn āyah tí ó sọ̀kalẹ̀ ṣíwájú Hijrah (āyah Mọkiyyah) rẹ́ àti gẹ́gẹ́ bí àwọn āyah ìdájọ́ kan tí ó sọ̀kalẹ̀ nínú àwọn ọdún ìparí nínú ìlú Mọdīnah ṣe pa àwọn āyah ìdájọ́ kan tí ó sọ̀kalẹ̀ nínú àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ nínú ìlú Mọdīnah rẹ́.