وَلَمَّا جَآءَ مُوسَىٰ لِمِيقَٰتِنَا وَكَلَّمَهُۥ رَبُّهُۥ قَالَ رَبِّ أَرِنِيٓ أَنظُرۡ إِلَيۡكَۚ قَالَ لَن تَرَىٰنِي وَلَٰكِنِ ٱنظُرۡ إِلَى ٱلۡجَبَلِ فَإِنِ ٱسۡتَقَرَّ مَكَانَهُۥ فَسَوۡفَ تَرَىٰنِيۚ فَلَمَّا تَجَلَّىٰ رَبُّهُۥ لِلۡجَبَلِ جَعَلَهُۥ دَكّٗا وَخَرَّ مُوسَىٰ صَعِقٗاۚ فَلَمَّآ أَفَاقَ قَالَ سُبۡحَٰنَكَ تُبۡتُ إِلَيۡكَ وَأَنَا۠ أَوَّلُ ٱلۡمُؤۡمِنِينَ ١٤٣
Walammā jā'a mūsā limīqātinā wakallamahū rabbuhū qāla rabbi arinī anzur ilayka qāla lan tarānī walākininzur ilal-jabali fa inistaqarra makānahū fasawfa tarānī falammā tajallā rabbuhū lil-jabali ja'alahū dakkan wakharra mūsā sa'iqan falammā afāqa qāla subhānaka tubtu ilayka wa ana awwalul-mu'minīn
Nígbà tí (Ànábì) Mūsā dé ní àkókò tí A fún un (fún ìbánisọ̀rọ̀ náà), Olúwa rẹ̀ sì bá a sọ̀rọ̀. (Ànábì Mūsā) sọ pé: “Olúwa mi, fi ara Rẹ hàn mí, kí èmi lè rí Ọ.” (Allāhu) sọ pé: “Ìwọ kò lè rí Mi. Ṣùgbọ́n wo àpáta (yìí), tí ó bá dúró ṣinṣin sí àyè rẹ̀, láìpẹ́ o máa rí Mi.” Nígbà tí Olúwa rẹ̀ sì (rọra) fi ara Rẹ̀ han àpáta, Ó sọ ọ́ di pẹ̀tẹ́lẹ̀.1 (Ànábì) Mūsā sì ṣubú lulẹ̀, ó dákú. Nígbà tí ó jí, ó sọ pé: “Mímọ́ ni fún Ọ, èmi ronú pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ. Èmi sì ni àkọ́kọ́ àwọn onígbàgbọ́ òdodo (ní àsìkò tèmi.)2
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Àpàta náà dọ́gba pẹ̀lú ilẹ̀ nígbà tí ìmọ́lẹ̀ kín-ínkín lára Allāhu - tó ga jùlọ - fara han àpàta. [2] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-’Ani‘ām; 6:14.