۞ وَوَٰعَدۡنَا مُوسَىٰ ثَلَٰثِينَ لَيۡلَةٗ وَأَتۡمَمۡنَٰهَا بِعَشۡرٖ فَتَمَّ مِيقَٰتُ رَبِّهِۦٓ أَرۡبَعِينَ لَيۡلَةٗۚ وَقَالَ مُوسَىٰ لِأَخِيهِ هَٰرُونَ ٱخۡلُفۡنِي فِي قَوۡمِي وَأَصۡلِحۡ وَلَا تَتَّبِعۡ سَبِيلَ ٱلۡمُفۡسِدِينَ ١٤٢
Wawā'adnā mūsā thalāthīna laylatan wa atmamnāhā bi'ashrin fatamma mīqātu rabbihī arba'īna laylatan waqāla mūsā li akhīhi hārūnakhlufnī fī qawmī wa aslih walā tattabi' sabīlal-mufsidīn
Àti pé A yan ọgbọ̀n òru fún (Ànábì) Mūsā. A tún fi mẹ́wàá kún un. Nítorí náà, àkókò (tí) Olúwa Rẹ̀(dá fún un fún ìbánisọ̀rọ̀) pé ní òru ogójì.1 (Ànábì) Mūsā sọ fún arákùnrin rẹ̀ Hārūn, pé: “Rólé dè mí láààrin àwọn ènìyàn mi. Kí o máa ṣe àtúnṣe. Má sì ṣe tẹ̀lé ọ̀nà àwọn òbìlẹ̀jẹ́.”
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Àwọn onitafsīr sọ pé, Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - gba ààwẹ̀ fún ogójì ọjọ́ láti gbaradì fún ìbànisọ̀rọ̀ náà. Ogójì ọjọ́ náà ni ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Thul-ƙọ'dah àti ọjọ́ mẹ́wàá àkọ́kọ́ nínú oṣù Thul-Hijjah.