فَأَنجَيۡنَٰهُ وَأَصۡحَٰبَ ٱلسَّفِينَةِ وَجَعَلۡنَٰهَآ ءَايَةٗ لِّلۡعَٰلَمِينَ ١٥
Fa anjaynāhu wa ashābas-safīnati waja'alnāhā āyatal lil-'ālamīn
A sì la òun àti àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú-omi. A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá.1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ǹjẹ́ ẹnì kan lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - di olúwa àti olùgbàlà nítorí pé Allāhu sọ nípa rẹ̀ pé “A sì ṣe wọ́n ní àmì fún gbogbo ẹ̀dá”? Rárá. Kí ló wá rọ́lu àwọn kan tí wọ́n sọ Ànábì Īsā di olùgbàlà?