وَمَآ أَرۡسَلۡنَا مِن قَبۡلِكَ مِن رَّسُولٍ إِلَّا نُوحِيٓ إِلَيۡهِ أَنَّهُۥ لَآ إِلَٰهَ إِلَّآ أَنَا۠ فَٱعۡبُدُونِ ٢٥
Wamā arsalnā min qablika mir rasūlin illā nūhī ilayhi annahū lā ilāha illā ana fa'budūn
A kò rán òjíṣẹ́ kan níṣẹ́ ṣíwájú rẹ àfi kí A fi ìmísí ránṣẹ́ sí i pé: “Dájúdájú kò sí ọlọ́hun kan tí ẹ gbọ́dọ̀ jọ́sìn fún ní ọ̀nà òdodo àyàfi Èmi (Allāhu). Nítorí náà, ẹ jọ́sìn fún Mi.”1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Āyah yìí ti fi hàn kedere pé, ìpèpè gbogbo àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu ni "at-taohīd", kì í ṣe "aṣṣirk".