Suratu Al-An'am, aaya 42

6:42

وَلَقَدۡ أَرۡسَلۡنَآ إِلَىٰٓ أُمَمٖ مِّن قَبۡلِكَ فَأَخَذۡنَٰهُم بِٱلۡبَأۡسَآءِ وَٱلضَّرَّآءِ لَعَلَّهُمۡ يَتَضَرَّعُونَ ٤٢

Walaqad arsalnā ilā umamim min qablika fa akhadhnāhum bil-ba'sā'i wad-darrā'i la'allahum yatadarra'ūn

Dájúdájú A ti ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ kan ṣíwájú rẹ. A sì fi àwọn ìpọ́njú àti àwọn àìlera gbá wọn mú nítorí kí wọ́n lè rawọ́ rasẹ̀ (sí Allāhu).1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìrawọ́-rasẹ̀ sí Allāhu ni pé, yíyẹpẹrẹ ara ẹni fún Un, pípáyà Rẹ̀ àti ríronú-pìwàdà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.