Suratu Al-An'am, aaya 128

6:128

وَيَوۡمَ يَحۡشُرُهُمۡ جَمِيعٗا يَٰمَعۡشَرَ ٱلۡجِنِّ قَدِ ٱسۡتَكۡثَرۡتُم مِّنَ ٱلۡإِنسِۖ وَقَالَ أَوۡلِيَآؤُهُم مِّنَ ٱلۡإِنسِ رَبَّنَا ٱسۡتَمۡتَعَ بَعۡضُنَا بِبَعۡضٖ وَبَلَغۡنَآ أَجَلَنَا ٱلَّذِيٓ أَجَّلۡتَ لَنَاۚ قَالَ ٱلنَّارُ مَثۡوَىٰكُمۡ خَٰلِدِينَ فِيهَآ إِلَّا مَا شَآءَ ٱللَّهُۚ إِنَّ رَبَّكَ حَكِيمٌ عَلِيمٞ ١٢٨

Wayawma yahshuruhum jamī'an yāma'sharal-jinni qadistakthartum minal-insi waqāla awliyā'uhum minal-insi rabbanastamta'a ba'dunā biba'din wabalaghnā ajalanal-ladhī ajjalta lanā qālan-nāru mathwākum khālidīna fīhā illā mā shā'allāhu inna rabbaka hakīmun 'alīm

(Rántí) Ọjọ́ tí (Allāhu) yóò kó gbogbo wọn jọ pátápátá, (Ó máa sọ pé): “Ẹ̀yin àwùjọ àlùjànnú, dájúdájú ẹ ti kó ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn sọnù.” Àwọn ọ̀rẹ́ wọn nínú àwọn ènìyàn yóò wí pé: “Olúwa wa, apá kan wa gbádùn apá kan ni. A sì ti lo àsìkò wa tí O bù fún wa (láti lò).” (Allāhu) sọ pé: “Iná ni ibùgbé yín; olùṣegbére ni yín nínú rẹ̀ àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́1. Dájúdájú Olúwa rẹ ni Ọlọ́gbọ́n, Onímọ̀.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Kíyè sí i, āyah yìí kò sọ pé “ إن شاء الله - tí Allāhu bá fẹ́ -.” Ohun tí ó sọ ni pé “إِلَّا مَا شَآءَ - àfi ohun tí Allāhu bá fẹ́ -.”