Suratu Al-Ahzab, aaya 26

33:26

وَأَنزَلَ ٱلَّذِينَ ظَٰهَرُوهُم مِّنۡ أَهۡلِ ٱلۡكِتَٰبِ مِن صَيَاصِيهِمۡ وَقَذَفَ فِي قُلُوبِهِمُ ٱلرُّعۡبَ فَرِيقٗا تَقۡتُلُونَ وَتَأۡسِرُونَ فَرِيقٗا ٢٦

Wa anzalal-ladhīna zāharūhum min ahlil-kitābi min sayāsīhim waqadhafa fī qulūbihimur-ru'ba farīqan taqtulūna wata'sirūna farīqā

(Allāhu) sì mú àwọn tó ṣèrànlọ́wọ́ fún (àwọn ọmọ ogun oníjọ) nínú àwọn onítírà sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú àwọn odi wọn. Ó sì ju ẹ̀rù sínú ọkàn wọn. Ẹ̀ ń pa igun kan (nínú wọn), ẹ sì ń kó igun kan lẹ́rú.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Àwọn ahlul-kitāb wọ̀nyẹn ni àwọn yẹhudi tí wọ́n ń jẹ́ banū Ƙuraeṭḥọh, tí wọ́n ń gbé nínú ìlú Mọdīnah. Àwọn wọ̀nyí mọ odi ńlá ńlá yípo àwọn ilé wọn fún ààbò ogun. Àwọn wọ̀nyí l’ó ṣe agbódegbà fún àwọn ọmọ ogun oníjọ. Lẹ́yìn tí Allāhu Alágbára sì dójú ti àwọn ọmọ ogun oníjọ tán, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - fàbọ̀ sórí wọn.