Suratu Yusuf, aaya 76

12:76

فَبَدَأَ بِأَوۡعِيَتِهِمۡ قَبۡلَ وِعَآءِ أَخِيهِ ثُمَّ ٱسۡتَخۡرَجَهَا مِن وِعَآءِ أَخِيهِۚ كَذَٰلِكَ كِدۡنَا لِيُوسُفَۖ مَا كَانَ لِيَأۡخُذَ أَخَاهُ فِي دِينِ ٱلۡمَلِكِ إِلَّآ أَن يَشَآءَ ٱللَّهُۚ نَرۡفَعُ دَرَجَٰتٖ مَّن نَّشَآءُۗ وَفَوۡقَ كُلِّ ذِي عِلۡمٍ عَلِيمٞ ٧٦

Fabada'a bi aw'iyatihim qabla wi'ā'i akhīhi thummastakhrajahā min wi'ā'i akhīhi kadhālika kidnā liyūsufa mā kāna liya'khudha akhāhu fī dīnil-maliki illā an yashā'allāhu narfa'u darajātim man nashā'u wafawqa kulli dhī 'ilmin 'alīm

Ó sì bẹ̀rẹ̀ (àyẹ̀wò) pẹ̀lú àpò wọn ṣíwájú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú un jáde láti inú àpò ọmọ-ìyá rẹ̀. Báyẹn ní A ṣe fún (Ànábì) Yūsuf ní ète dá. Kò lè fi òfin ọba mú ọmọ-ìyá rẹ̀ àfi tí Allāhu bá fẹ́.1 À ń ṣàgbéga àwọn ipò fún ẹni tí A bá fẹ́. Onímọ̀ wà lókè gbogbo onímọ̀.2

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Kò sí òfin sísọ olè dí ẹrú olóhun nínú ìlú Misrọ. Àmọ́ Allāhu fẹ́ kí Ànábì Yūsūf - kí ọlà Allāhu máa bá a - mú ọmọ ìyá rẹ̀ mọ́lẹ̀. Allāhu sì fi ìdàjọ́ tí wọ́n máa lò fún "olè" sí ẹnu àwọn ọmọ Ànábì Ya'ƙūb - kí ọlà Allāhu máa bá a -. Ohun tí Allāhu fẹ́ sì wá sí ìmúṣẹ. [2] Ìyẹn ni pé, ẹ̀dá fi ipò àti ìmọ̀ ga jura wọn títí ipò àti ìmọ̀ fi pin sí ọ̀dọ̀ Allāhu Ọba tí Ó ga jùlọ nínú ipò àti ìmọ̀.