Suratu Yunus, aaya 22

10:22

هُوَ ٱلَّذِي يُسَيِّرُكُمۡ فِي ٱلۡبَرِّ وَٱلۡبَحۡرِۖ حَتَّىٰٓ إِذَا كُنتُمۡ فِي ٱلۡفُلۡكِ وَجَرَيۡنَ بِهِم بِرِيحٖ طَيِّبَةٖ وَفَرِحُواْ بِهَا جَآءَتۡهَا رِيحٌ عَاصِفٞ وَجَآءَهُمُ ٱلۡمَوۡجُ مِن كُلِّ مَكَانٖ وَظَنُّوٓاْ أَنَّهُمۡ أُحِيطَ بِهِمۡ دَعَوُاْ ٱللَّهَ مُخۡلِصِينَ لَهُ ٱلدِّينَ لَئِنۡ أَنجَيۡتَنَا مِنۡ هَٰذِهِۦ لَنَكُونَنَّ مِنَ ٱلشَّٰكِرِينَ ٢٢

Huwal-ladhī yusayyirukum fil-barri wal-bahri hattā idhā kuntum fil-fulki wajarayna bihim birīhin tayyibatin wafarihū bihā jā'athā rīhun 'āsifun wajā'ahumul-mawju min kulli makānin wazannū annahum uhīta bihim da'awullāha mukhlisīna lahud-dīna la in anjaytanā min hādhihī lanakūnanna minash-shākirīn

(Allāhu) Òun ni Ẹni tí Ó mu yín rìn lórí ilẹ̀ àti ní ojú omi, títí di ìgbà tí ẹ bá wà nínú ọkọ̀ ojú-omi, tí ó ń gbé wọn lọ pẹ̀lú atẹ́gùn tó dára, inú wọn yó sì máa dùn sí i. (Àmọ́) atẹ́gùn líle kọ lù ú, ìgbì omi dé bá wọn ní gbogbo àyè, wọ́n sì mọ̀ pé dájúdájú wọ́n ti fi (àdánwò) yí àwọn po, wọ́n máa pe Allāhu lẹ́ni tí yóò máa fi àfọ̀mọ́-ọkàn (àníyàn mímọ́) ṣe ẹ̀sìn fún Un1 (wọ́n sì máa sọ pé): “Dájúdájú tí O bá fi lè gbà wá là níbi èyí, dájúdájú a máa wà nínú àwọn olùdúpẹ́.”

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Nínú āyah yìí, wọ́n pe “àdúà” ní “ẹ̀sìn”. Ó tún jẹyọ bẹ́ẹ̀ nínú sūrah Gāfir; 40:60. Èyí ti fi hàn kedere pé, ẹ̀sìn ni àdúà ṣíṣe. Nítorí náà, bí ẹlẹ́sìn tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn ’Islām bá pe mùsùlùmí kan lọ síbi àdúà lórí ìlànà ẹ̀sìn kèfèrí, yálà ìlànà abọ̀rìṣà tàbí ìlànà nasọ̄rọ̄, ó ń dá ète láti pe mùsùlùmí yẹn lọ sínú ẹ̀sìn kèfèrí rẹ̀ ni. Bí mùsùlùmí yẹn bá jẹ́pè kèfèrí náà, òun náà ti di kèfèrí nìyẹn.