Suratu Yasin, aaya 45

36:45

وَإِذَا قِيلَ لَهُمُ ٱتَّقُواْ مَا بَيۡنَ أَيۡدِيكُمۡ وَمَا خَلۡفَكُمۡ لَعَلَّكُمۡ تُرۡحَمُونَ ٤٥

Wa idhā qīla lahumut-taqū mā bayna aydīkum wamā khalfakum la'allakum turhamūn

(Wọ́n máa gbúnrí) nígbà tí A bá sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín1 àti ohun tó wà lẹ́yìn yín2 nítorí kí A lè kẹ yín.”

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 “Ẹ ṣọ́ra fún ohun tó wà níwájú yín”; ohun tí ó wà níwájú wọn ni àwọn àpẹ̀ẹrẹ irú ìyà àti ìparun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n pé ọ̀rọ̀ Allahu - Ọba Òdodo - ní irọ́ ṣíwájú wọn. [2] “àti ohun tó wà lẹ́yìn yín”; ohun tí ó wà lẹ́yìn wọn ni ìyà ọjọ́ Àjíǹde, ìyà Iná tí ó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n pé ọ̀rọ̀ Allahu - Ọba Òdodo - ní irọ́.