إِنِّيٓ أَنَا۠ رَبُّكَ فَٱخۡلَعۡ نَعۡلَيۡكَ إِنَّكَ بِٱلۡوَادِ ٱلۡمُقَدَّسِ طُوٗى ١٢
Innī ana rabbuka fakhla' na'layka innaka bil-wādil-muqaddasi tuwā
Dájúdájú Èmi ni Olúwa rẹ. Nítorí náà, bọ́ bàtà rẹ méjèèjì sílẹ̀.1 Dájúdájú ìwọ wà ní àfonífojì mímọ́, Tuwā.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìdí tí Allāhu - tó ga jùlọ - fi pa á láṣẹ fún Ànábì Mūsā - kí ọlà Allāhu máa bá a - láti bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọmọ Mọs‘ūd - kí Allāhu yọ́nú sí i - ṣe gbà á wá ni pé, awọ òkúǹbete kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí wọn kò pa lósè ni wọ́n fi ṣe bàtà náà.