Suratu Sad, aaya 39

38:39

هَٰذَا عَطَآؤُنَا فَٱمۡنُنۡ أَوۡ أَمۡسِكۡ بِغَيۡرِ حِسَابٖ ٣٩

Hādhā 'atā'unā famnun aw amsik bighayri hisāb

Èyí ni ọrẹ Wa. Nítorí náà, fi tọrẹ tàbí kí ó mú un dání1 láì níí ní ìṣírò.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Gbólóhùn yìí “Èyí ni ọrẹ Wa.” Ó túmọ̀ sí “èyí ni àwọn dúkìá ayé tí A fi ta ọ́ ní ọrẹ”. Ìtúmọ̀ yìí sì ni mo lò. Àmọ́ “Èyí ni ọrẹ Wa.” tún túmọ̀ sí “èyí ni àwọn àlùjànnú tí A fi ta ọ́ ní ọrẹ.”