فَهَلۡ عَسَيۡتُمۡ إِن تَوَلَّيۡتُمۡ أَن تُفۡسِدُواْ فِي ٱلۡأَرۡضِ وَتُقَطِّعُوٓاْ أَرۡحَامَكُمۡ ٢٢
Fahal 'asaytum in tawallaytum an tufsidū fil-ardi watuqatti'ū arhāmakum
Ó súnmọ́ pé tí ẹ̀yin bá kọ̀yìn sí ogun ẹ̀sìn, (ẹ̀ ń lọ sí oko ìparun nìyẹn, ẹ sì máa padà síbi ìwà ìgbà àìmọ̀kan) tí ẹ̀yin yóò máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀, tí ẹ óò sì máa já okùn-ìbí yín?1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí, “Ó súnmọ́ pé (ẹ̀yin aláìsàn ọkàn wọ̀nyí) bí ẹ bá dé orí ipò àṣẹ, ẹ óò máa ṣèbàjẹ́ lórí ilẹ̀ àti pé ẹ óò máa já okùn-ìbí yín?”