أَسۡمِعۡ بِهِمۡ وَأَبۡصِرۡ يَوۡمَ يَأۡتُونَنَا لَٰكِنِ ٱلظَّٰلِمُونَ ٱلۡيَوۡمَ فِي ضَلَٰلٖ مُّبِينٖ ٣٨
Asmi' bihim wa absir yawma ya'tūnanā lākiniz-zālimūnal-yawma fī dalālim mubīn
Kí ni wọn kò níí gbọ́, kí sì ni wọn kò níí rí ní ọjọ́ tí wọn yóò wá bá Wa!1 Ṣùgbọ́n àwọn alábòsí ní ọjọ́ òní (ní ilé ayé) wà nínú ìṣìnà pọ́nńbélé.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìyẹn ni pé, bí àwọn aláìgbàgbọ́ kò bá lo ìgbọ́rọ̀ wọn fún gbígbọ́ òdodo, tí wọn kò sì lo ìríran wọn fún rírí òdodo ní ilé ayé yìí, wọn yóò fi ìgbọ́rọ̀ wọn gbọ́ òdodo ketekete, wọn yó sì fi ìríran wọn rí òdodo kedere pẹ̀lú àbámọ̀ ní ọ̀run nítorí pé, Ọjọ́ ẹ̀san ni ọjọ́ náà.