Amana ar-Rasul

Ìtumọ̀: Yoruba Translation - Abu Rahimah Mikael

ءَامَنَ ٱلرَّسُولُ بِمَآ أُنزِلَ إِلَيۡهِ مِن رَّبِّهِۦ وَٱلۡمُؤۡمِنُونَۚ كُلٌّ ءَامَنَ بِٱللَّهِ وَمَلَٰٓئِكَتِهِۦ وَكُتُبِهِۦ وَرُسُلِهِۦ لَا نُفَرِّقُ بَيۡنَ أَحَدٖ مِّن رُّسُلِهِۦۚ وَقَالُواْ سَمِعۡنَا وَأَطَعۡنَاۖ غُفۡرَانَكَ رَبَّنَا وَإِلَيۡكَ ٱلۡمَصِيرُ ٢٨٥

Āmanar-rasūlu bimā unzila ilayhi mir rabbihī wal-mu'minūna kullun āmana billāhi wamalā'ikatihī wakutubihī warusulihī lā nufarriqu bayna ahadim mir rusulihī waqālū sami'nā wa ata'nā ghufrānaka rabbanā wa ilaykal-masīr

Òjíṣẹ́ náà - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a - gbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ̀. Àwọn onígbàgbọ́ òdodo náà (gbàgbọ́ nínú rẹ̀). Ẹnì kọ̀ọ̀kan (wọn) gbàgbọ́ nínú Allāhu, àwọn mọlāika Rẹ̀, àwọn Tírà Rẹ̀ àti àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀.1 A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú àwọn Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́ (àṣẹ), a sì tẹ̀lé (àṣẹ). À ń tọrọ àforíjìn Rẹ, Olúwa wa. Ọ̀dọ̀ Rẹ sì ni àbọ̀ ẹ̀dá.”

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Kíyè sí i, ìgbàgbọ́ àwa ọmọlẹ́yìn Ànábì Muhammad - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá a - nínú àwọn Tírà àti àwọn Òjíṣẹ́ tó ṣíwájú - kí ìkẹ́ àti ọlà máa bá wọn - tí gbogbo wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn ’Islām kò túmọ̀ sí títẹ̀lé wọn nínú ìlànà ìjọ́sìn wọn àti ìdájọ́ ṣíṣe ní àsìkò yìí.

لَا يُكَلِّفُ ٱللَّهُ نَفۡسًا إِلَّا وُسۡعَهَاۚ لَهَا مَا كَسَبَتۡ وَعَلَيۡهَا مَا ٱكۡتَسَبَتۡۗ رَبَّنَا لَا تُؤَاخِذۡنَآ إِن نَّسِينَآ أَوۡ أَخۡطَأۡنَاۚ رَبَّنَا وَلَا تَحۡمِلۡ عَلَيۡنَآ إِصۡرٗا كَمَا حَمَلۡتَهُۥ عَلَى ٱلَّذِينَ مِن قَبۡلِنَاۚ رَبَّنَا وَلَا تُحَمِّلۡنَا مَا لَا طَاقَةَ لَنَا بِهِۦۖ وَٱعۡفُ عَنَّا وَٱغۡفِرۡ لَنَا وَٱرۡحَمۡنَآۚ أَنتَ مَوۡلَىٰنَا فَٱنصُرۡنَا عَلَى ٱلۡقَوۡمِ ٱلۡكَٰفِرِينَ ٢٨٦

Lā yukallifullāhu nafsan illā wus'ahā lahā mā kasabat wa'alayhā maktasabat rabbanā lā tu'ākhidhnā in nasīnā aw akhta'nā rabbanā walā tahmil 'alaynā isran kamā hamaltahū 'alal-ladhīna min qablinā rabbanā walā tuhammilnā mā lā tāqata lanā bihī wa'fu 'annā waghfir lanā warhamnā anta mawlānā fansurnā 'alal-qawmil-kāfirīn

Allāhu kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. (Ẹ̀san) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (rere) ń bẹ fún un. (Ìyà) ohun tí ó ṣe níṣẹ́ (ibi) ń bẹ fún un pẹ̀lú. Olúwa wa, má ṣe mú wa tí a bá gbàgbéra tàbí (tí) a bá ṣàṣìṣe. Olúwa wa, má ṣe di ẹrù tó wúwo lé wa lórí, gẹ́gẹ́ bí O ṣe dì í ru àwọn tó ṣíwájú wa. Olúwa wa, má ṣe dìrù wá ohun tí kò sí agbára rẹ̀ fún wa. Ṣàmójú kúrò fún wa, foríjìn wá, kí O sì ṣàánú wa. Ìwọ ni Aláfẹ̀yìntì wa. Nítorí náà, ràn wá lọ́wọ́ lórí ìjọ aláìgbàgbọ́.

Kíkà ní lẹ́tà Látìn jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún kíkà tí Qabas kọ láti inú èdè Lárúbáwá. Kọ́ àwọn lẹ́tà Lárúbáwá àti tajwīd fún ìpè tó péye.

Ka gbogbo Suratu Al-Baqarah

Àwọn ìbéèrè

Níbo ni Amana ar-Rasul wà nínú Al-Kurani?

Amana ar-Rasul wà nínú Suratu Al-Baqarah, 2:285-286.