وَأَقِمِ ٱلصَّلَوٰةَ طَرَفَيِ ٱلنَّهَارِ وَزُلَفٗا مِّنَ ٱلَّيۡلِۚ إِنَّ ٱلۡحَسَنَٰتِ يُذۡهِبۡنَ ٱلسَّيِّـَٔاتِۚ ذَٰلِكَ ذِكۡرَىٰ لِلذَّٰكِرِينَ ١١٤
Wa aqimis-salawāta tarafayin-nahāri wazulafam minal-layli innal-hasanāti yudhhibnas-sayyi'āti dhālika dhikrā lidh-dhākirīn
Kírun ní etí ọ̀sán méjèèjì1 àti ní abala kan nínú òru2. Dájúdájú àwọn iṣẹ́ rere ń pa àwọn iṣẹ́ aburú rẹ́. Ìyẹn ni ìrántí fún àwọn olùrántí (Allāhu).
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìyẹn ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sán àti ìparí ọ̀sán. Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sán dúró fún lílà al-fajr fún ìrun Subh. Ìparí ọ̀sán dúró fún ìrun Ṭḥuhr àti ‘Asr. [2] Ìyẹn ni abala ìbẹ̀rẹ̀ òru. Èyí dúró fún ìrun Mọgrib àti ‘Iṣā’.