إِنَّ ٱلَّذِينَ يُلۡحِدُونَ فِيٓ ءَايَٰتِنَا لَا يَخۡفَوۡنَ عَلَيۡنَآۗ أَفَمَن يُلۡقَىٰ فِي ٱلنَّارِ خَيۡرٌ أَم مَّن يَأۡتِيٓ ءَامِنٗا يَوۡمَ ٱلۡقِيَٰمَةِۚ ٱعۡمَلُواْ مَا شِئۡتُمۡ إِنَّهُۥ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٌ ٤٠
Innal-ladhīna yulhidūna fī āyātinā lā yakhfawna 'alaynā afaman yulqā fin-nāri khayrun am man ya'tī āminan yawmal-qiyāmati'malū mā shi'tum innahū bimā ta'malūna basīr
Dájúdájú àwọn tó ń darí àwọn āyah Wa kọ ọ̀nà òdì,1 wọn kò pamọ́ fún Wa. Ṣé ẹni tí wọ́n máa jù sínú Iná l’ó lóore jùlọ ni tàbí ẹni tí ó máa wá ní olùfàyàbalẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde? Ẹ máa ṣe ohun tí ẹ bá fẹ́. Dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Nínú dídarí àwọn āyah al-Ƙur’ān kọ ọ̀nà òdì ni fífún āyah kan ní ìtúmọ̀ òdì, fífi āyah kan tako āyah mìíràn, lílo āyah kan ní àyè tí kò jẹmọ́ ọn, fífi āyah kan ṣe ẹ̀fẹ̀, ṣíṣe àtakò sí āyah kan, pípa ọ̀rọ̀ al-Ƙur’ān tì láti tẹ̀lé ìròrí, ìṣe àti àṣà ìgbà-àìmọ̀kan àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.