Suratu Fussilat, aaya 14

41:14

إِذۡ جَآءَتۡهُمُ ٱلرُّسُلُ مِنۢ بَيۡنِ أَيۡدِيهِمۡ وَمِنۡ خَلۡفِهِمۡ أَلَّا تَعۡبُدُوٓاْ إِلَّا ٱللَّهَۖ قَالُواْ لَوۡ شَآءَ رَبُّنَا لَأَنزَلَ مَلَٰٓئِكَةٗ فَإِنَّا بِمَآ أُرۡسِلۡتُم بِهِۦ كَٰفِرُونَ ١٤

Idh jā'athumur-rusulu mim bayni aydīhim wamin khalfihim allā ta'budū illallāha qālū law shā'a rabbunā la anzala malā'ikatan fa innā bimā ursiltum bihī kāfirūn

Nígbà tí àwọn Òjíṣẹ́ wọn wá bá wọn níwájú wọn àti lẹ́yìn wọn,1 (wọ́n sọ) pé: “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jọ́sìn fún ẹnì kan àyàfi Allāhu.” Wọ́n wí pé: “Tí ó bá jẹ́ pé Olúwa wa bá fẹ́ ni, ìbá sọ àwọn mọlāika kalẹ̀ (fún ìpèpè yìí). Dájúdájú àwa jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ohun tí wọ́n fi ran yín níṣẹ́.”

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 “níwájú wọn” túmọ̀ sí pé àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu - kí ọlà Allāhu máa bá wọn - wá bá àwọn bàbá ńlá wọn, “lẹ́yìn wọn” sì túmọ̀ sí pé àwọn Òjíṣẹ́ Allāhu tún wá bá àwọn àrọ́mọdọ́mọ wọn lẹ́yìn ìparun àwọn bàbá ńlá wọn.