Suratu At-Tawbah, aaya 80

9:80

ٱسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ أَوۡ لَا تَسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ إِن تَسۡتَغۡفِرۡ لَهُمۡ سَبۡعِينَ مَرَّةٗ فَلَن يَغۡفِرَ ٱللَّهُ لَهُمۡۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمۡ كَفَرُواْ بِٱللَّهِ وَرَسُولِهِۦۗ وَٱللَّهُ لَا يَهۡدِي ٱلۡقَوۡمَ ٱلۡفَٰسِقِينَ ٨٠

Istaghfir lahum aw lā tastaghfir lahum in tastaghfir lahum sab'īna marratan falan yaghfirallāhu lahum dhālika bi annahum kafarū billāhi warasūlihī wallāhu lā yahdil-qawmal-fāsiqīn

Yálà o tọrọ àforíjìn fún wọ́n tàbí o ò tọrọ àforíjìn fún wọn - kódà kí o tọrọ àforíjìn fún wọn nígbà ààdọ́rin - Allāhu kò níí foríjìn wọ́n.1 Ìyẹn nítorí pé, dájúdájú wọ́n ṣàì gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Òjísẹ́ Rẹ̀. Allāhu kò níí fi ọ̀nà mọ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn nípa ti àwọn munāfiki, kì í ṣe nípa ti àwọn mùsùlùmí onígbàgbọ́ òdodo.