Suratu At-Tawbah, aaya 59

9:59

وَلَوۡ أَنَّهُمۡ رَضُواْ مَآ ءَاتَىٰهُمُ ٱللَّهُ وَرَسُولُهُۥ وَقَالُواْ حَسۡبُنَا ٱللَّهُ سَيُؤۡتِينَا ٱللَّهُ مِن فَضۡلِهِۦ وَرَسُولُهُۥٓ إِنَّآ إِلَى ٱللَّهِ رَٰغِبُونَ ٥٩

Walaw annahum radū mā ātāhumullāhu warasūluhū waqālū hasbunallāhu sayu'tīnallāhu min fadlihī warasūluhū innā ilallāhi rāghibūn

Àti pé (ìbá lóore fún wọn) tí ó bá jẹ́ pé dájúdájú wọ́n yọ́nú sí ohun tí Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ fún wọn, kí wọ́n sì sọ pé: “Allāhu tó wa. Allāhu yó sì fún wa nínú oore àjùlọ Rẹ̀ àti pé Òjíṣẹ́ Rẹ̀ (sì máa pín ọrẹ)1, dájúdájú ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni àwa ń wá oore sí.”

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 N̄ǹkan tí āyah yìí ń sọ ni pé, Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - lẹ́tọ̀ọ́ sí pípín àwọn ọrẹ tí Allāhu pín kàn án nínú àwọn oore ayé àrígbámú yálà nípasẹ̀ ọrọ̀ ogun, zakāh gbígbà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.