ضَرَبَ لَكُم مَّثَلٗا مِّنۡ أَنفُسِكُمۡۖ هَل لَّكُم مِّن مَّا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُكُم مِّن شُرَكَآءَ فِي مَا رَزَقۡنَٰكُمۡ فَأَنتُمۡ فِيهِ سَوَآءٞ تَخَافُونَهُمۡ كَخِيفَتِكُمۡ أَنفُسَكُمۡۚ كَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ ٱلۡأٓيَٰتِ لِقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ ٢٨
Daraba lakum mathalam min anfusikum hal lakum mim mā malakat aymānukum min shurakā'a fī mā razaqnākum fa antum fīhi sawā'un takhāfūnahum kakhīfatikum anfusakum kadhālika nufassilul-āyāti liqawmin ya'qilūn
(Allāhu) ṣàkàwé kan fún yín nípa ara yín. Ǹjẹ́ ẹ ní akẹgbẹ́ nínú àwọn ẹrú yín lórí ohun tí A fún yín ní arísìkí, tí ẹ jọ máa pín (dúkìá náà) ní dọ́gban̄dọ́gba, tí ẹ ó sì máa páyà wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ń páyà ara yin náà? Báyẹn ni A ṣe ń ṣ’àlàyé àwọn āyah fún ìjọ tó ń ṣe làákàyè.1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Èsì sí àkàwé yìí ni pé, kò sí olówó ẹrú tí ó máa sọ ẹrú rẹ̀ di ẹgbẹ́ rẹ̀ lórí dúkìá rẹ̀. Ṣebí dúkìá náà ni ẹrú jẹ́ fún olówó ẹrú. Nítorí náà, kò lè sí ẹni tí Allāhu - tó ga jùlọ - máa sọ di ẹgbẹ́ Rẹ̀ láààrin gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀. Ẹrú Rẹ̀ sì ni gbogbo ẹ̀dá Rẹ̀.