Suratu Ar-Ra'd, aaya 4

13:4

وَفِي ٱلۡأَرۡضِ قِطَعٞ مُّتَجَٰوِرَٰتٞ وَجَنَّٰتٞ مِّنۡ أَعۡنَٰبٖ وَزَرۡعٞ وَنَخِيلٞ صِنۡوَانٞ وَغَيۡرُ صِنۡوَانٖ يُسۡقَىٰ بِمَآءٖ وَٰحِدٖ وَنُفَضِّلُ بَعۡضَهَا عَلَىٰ بَعۡضٖ فِي ٱلۡأُكُلِۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ ٤

Wafil-ardi qita'um mutajāwirātun wajannātum min a'nābin wazar'un wanakhīlun sinwānun waghayru sinwānin yusqā bimā'in wāhidin wanufaddilu ba'dahā 'alā ba'din fil-ukuli inna fī dhālika la'āyātil liqawmin ya'qilūn

Ó tún wà nínú ilẹ̀ àwọn abala-abala ilẹ̀ (oníran-ànran) tó wà nítòsí ara wọn1 àti àwọn ọgbà oko àjàrà, irúgbìn àti igi dàbínù tó pẹka àti èyí tí kò pẹka, tí wọ́n ń fún wọn ní omi ẹyọ kan mu. (Síbẹ̀síbẹ̀) A ṣe àjùlọ fún apá kan rẹ̀ lórí apá kan níbi àwọn èso wọn. Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìyẹn fún ìjọ tó ní làákàyè.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Bíi ilẹ̀ yanrìn nítòsí ilẹ̀ amọ̀, ilẹ́ yangí nítòsí ilẹ̀ tí kì í ṣe ilẹ̀ yangí, ilẹ̀ tó lọ́ràá nítòsí ilẹ̀ tó sá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.