Suratu An-Nur, aaya 35

24:35

۞ ٱللَّهُ نُورُ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِۚ مَثَلُ نُورِهِۦ كَمِشۡكَوٰةٖ فِيهَا مِصۡبَاحٌۖ ٱلۡمِصۡبَاحُ فِي زُجَاجَةٍۖ ٱلزُّجَاجَةُ كَأَنَّهَا كَوۡكَبٞ دُرِّيّٞ يُوقَدُ مِن شَجَرَةٖ مُّبَٰرَكَةٖ زَيۡتُونَةٖ لَّا شَرۡقِيَّةٖ وَلَا غَرۡبِيَّةٖ يَكَادُ زَيۡتُهَا يُضِيٓءُ وَلَوۡ لَمۡ تَمۡسَسۡهُ نَارٞۚ نُّورٌ عَلَىٰ نُورٖۚ يَهۡدِي ٱللَّهُ لِنُورِهِۦ مَن يَشَآءُۚ وَيَضۡرِبُ ٱللَّهُ ٱلۡأَمۡثَٰلَ لِلنَّاسِۗ وَٱللَّهُ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٞ ٣٥

Allāhu nūrus-samāwāti wal-ardi mathalu nūrihī kamishkawātin fīhā misbāhunil-misbāhu fī zujājatiniz-zujājatu ka annahā kawkabun durriyyun yūqadu min shajaratim mubārakatin zaytūnatil lā sharqiyyatin walā gharbiyyatin yakādu zaytuhā yudī'u walaw lam tamsashu nārun nūrun 'alā nūrin yahdillāhu linūrihī man yashā'u wayadribullāhul-amthāla lin-nāsi wallāhu bikulli shay'in 'alīm

Allāhu ni Olùtan-ìmọ́lẹ̀ sínú àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀. Àpèjúwe ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ dà bí òpó àtùpà kan tí àtùpà wà nínú rẹ̀. Àtùpà náà sì wà nínú díńgí. Díńgí náà dà bí ìràwọ̀ kan tó ń tàn yànrànyànràn. Wọ́n ń tan (ìmọ́lẹ̀ náà) láti ara igi ìbùkún kan, igi zaetūn, tí kò gba ìmọ́lẹ̀ ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn (nìkan mọ).1 Epo rẹ̀ fẹ́rẹ̀ tànmọ́lẹ̀, iná ìbáà má dé ibẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ lórí ìmọ́lẹ̀ ni.2 Allāhu ń tọ́ ẹnikẹ́ni tí Ó bá fẹ́ sí (ọ̀nà) ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀. Allāhu ń fi àwọn àkàwé lélẹ̀ fún àwọn ènìyàn. Allāhu sì ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, kò gba ìmọ́lẹ̀ ìlà òòrùn àti ìwọ̀ òòrùn nìkan mọ bí kò ṣe pé, ó ń gba ìmọ́lẹ̀ sára ní gbogbo àyíká rẹ̀. [2] Ìyẹn ni pé, ó ń dá mú ìmọ́lẹ̀ tirẹ̀ wá. Bí wọ́n bá tún tan iná sí i lára, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tún máa lágbára sí i gan-an.