وَلَا تَتَمَنَّوۡاْ مَا فَضَّلَ ٱللَّهُ بِهِۦ بَعۡضَكُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖۚ لِّلرِّجَالِ نَصِيبٞ مِّمَّا ٱكۡتَسَبُواْۖ وَلِلنِّسَآءِ نَصِيبٞ مِّمَّا ٱكۡتَسَبۡنَۚ وَسۡـَٔلُواْ ٱللَّهَ مِن فَضۡلِهِۦٓۚ إِنَّ ٱللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيۡءٍ عَلِيمٗا ٣٢
Walā tatamannaw mā faddalallāhu bihī ba'dakum 'alā ba'dil lir-rijāli nasībum mimmaktasabū walin-nisā'i nasībum mimmaktasabna was'alullāha min fadlihī innallāha kāna bikulli shay'in 'alīmā
Ẹ má ṣe jẹ̀rankàn ohun tí Allāhu fi ṣ’oore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan.1 Ìpín (ẹ̀san) ń bẹ fún àwọn ọkùnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́, ìpín (ẹ̀san) sì ń bẹ fún àwọn obìnrin nípa ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Kí ẹ sì tọrọ lọ́dọ̀ Allāhu nínú àlékún oore Rẹ̀. Dájúdájú Allāhu ń jẹ́ Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Āyah yìí sọ̀kalẹ̀ nítorí bí àwọn obìnrin kan ṣe ń jẹ̀rankàn pé kí àwọn obìnrin àti àwọn ọkùnrin dìjọ wà ní ipò orí-ò-jorí. Allāhu sì jẹ́ kí ó yé wa pé kò rí bẹ́ẹ̀ rárá àfi níbi iṣẹ́ ìjọ́sìn àti ẹ̀san rẹ̀.