Suratu An-Nahl, aaya 71

16:71

وَٱللَّهُ فَضَّلَ بَعۡضَكُمۡ عَلَىٰ بَعۡضٖ فِي ٱلرِّزۡقِۚ فَمَا ٱلَّذِينَ فُضِّلُواْ بِرَآدِّي رِزۡقِهِمۡ عَلَىٰ مَا مَلَكَتۡ أَيۡمَٰنُهُمۡ فَهُمۡ فِيهِ سَوَآءٌۚ أَفَبِنِعۡمَةِ ٱللَّهِ يَجۡحَدُونَ ٧١

Wallāhu faddala ba'dakum 'alā ba'din fir-rizqi famal-ladhīna fuddilū birāddī rizqihim 'alā mā malakat aymānuhum fahum fīhi sawā'un afabini'matillāhi yajhadūn

Allāhu l’Ó ṣoore àjùlọ fún apá kan yín lórí apá kan nínú arísìkí. Bẹ́ẹ̀, àwọn tí A fún ní oore àjùlọ, wọn kì í fún àwọn ẹrú wọn ní arísìkí wọn, nítorí kí wọ́n má baà wà ní dọ́gban̄dọ́gba pẹ̀lú wọn níbi arísìkí!1 Nítorí náà, ṣe ìdẹ̀ra Allāhu ni wọn yóò máa takò?

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Àkàwé kan nìyí tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - fi lélẹ̀ fún àwọn ọ̀ṣẹbọ láti pe làákàyè wọn sí ohun tí wọn kò lè gbà, àmọ́ tí wọ́n ń fi lọ Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā -.