ٱسۡلُكۡ يَدَكَ فِي جَيۡبِكَ تَخۡرُجۡ بَيۡضَآءَ مِنۡ غَيۡرِ سُوٓءٖ وَٱضۡمُمۡ إِلَيۡكَ جَنَاحَكَ مِنَ ٱلرَّهۡبِۖ فَذَٰنِكَ بُرۡهَٰنَانِ مِن رَّبِّكَ إِلَىٰ فِرۡعَوۡنَ وَمَلَإِيْهِۦٓۚ إِنَّهُمۡ كَانُواْ قَوۡمٗا فَٰسِقِينَ ٣٢
Usluk yadaka fī jaybika takhruj baydā'a min ghayri sū'in wadmum ilayka janāhaka minar-rahbi fadhānika burhānāni mir rabbika ilā fir'awna wamala'ihī innahum kānū qawman fāsiqīn
Ti ọwọ́ rẹ bọ igbá-àyà ẹ̀wù rẹ, ó sì máa jáde ní funfun tí kì í ṣe ti aburú. Pa ọwọ́ rẹ mọ́ra níbi ẹ̀rù.1 Nítorí náà, àwọn ẹ̀rí méjì nìwọ̀nyí láti ọ̀dọ̀ Olúwa rẹ sí Fir‘aon àti àwọn ìjòyè rẹ̀. Dájúdájú wọ́n jẹ́ ìjọ òbìlẹ̀jẹ́.”
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìyẹn ni pé, tí ọpá rẹ bá yí padà, tó di ejò níwájú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ẹ̀rù sì ń ba ìwọ náà, pa ọwọ́ rẹ mọ́ra láti fi yọ ẹ̀rù náà kúrò nínú ọkàn rẹ.