Suratu Al-Qamar, aaya 9

54:9

۞ كَذَّبَتۡ قَبۡلَهُمۡ قَوۡمُ نُوحٖ فَكَذَّبُواْ عَبۡدَنَا وَقَالُواْ مَجۡنُونٞ وَٱزۡدُجِرَ ٩

Kaddhabat qablahum qawmu nūhin fakaddhabū 'abdanā waqālū majnūnun wazdujir

Ìjọ (Ànábì) Nūh pe òdodo ní irọ́ ṣíwájú wọn. Nígbà náà, wọ́n pe ẹrúsìn Wa ní òpùrọ́. Wọ́n sì wí pé: “Wèrè ni.” Wọ́n sì kọ̀ fún un pẹ̀lú ohùn líle.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, wọ́n fi ohùn líle kọ òdodo sílẹ̀ fún Ànábì Nūh - kí ọlà Allāhu máa bá a - ní kíkọ̀ àlésá-sẹ́yìn fún wọn nípasẹ̀ sísọ ọ̀rọ̀ burúkú sí i, híhalẹ̀ mọ̀ ọn, dídúnkokò mọ́ ọn nítorí kí ó lè máa wò wọ́n níran.