يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ لَا تَقۡتُلُواْ ٱلصَّيۡدَ وَأَنتُمۡ حُرُمٞۚ وَمَن قَتَلَهُۥ مِنكُم مُّتَعَمِّدٗا فَجَزَآءٞ مِّثۡلُ مَا قَتَلَ مِنَ ٱلنَّعَمِ يَحۡكُمُ بِهِۦ ذَوَا عَدۡلٖ مِّنكُمۡ هَدۡيَۢا بَٰلِغَ ٱلۡكَعۡبَةِ أَوۡ كَفَّٰرَةٞ طَعَامُ مَسَٰكِينَ أَوۡ عَدۡلُ ذَٰلِكَ صِيَامٗا لِّيَذُوقَ وَبَالَ أَمۡرِهِۦۗ عَفَا ٱللَّهُ عَمَّا سَلَفَۚ وَمَنۡ عَادَ فَيَنتَقِمُ ٱللَّهُ مِنۡهُۚ وَٱللَّهُ عَزِيزٞ ذُو ٱنتِقَامٍ ٩٥
Yā'ayyuhal-ladhīna āmanū lā taqtulus-sayda wa antum hurumun waman qatalahū minkum muta'ammidan fajazā'um mithlu mā qatala minan-na'ami yahkumu bihī dhawā 'adlim minkum hadyā bālighal-ka'bati aw kaffāratun ta'āmu masākīna aw 'adlu dhālika siyāmal liyadhūqa wabāla amrihī 'afallāhu 'ammā salafa waman 'āda fayantaqimullāhu minhu wallāhu 'azīzun dhuntiqām
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ má ṣe pa ẹran-ìgbẹ́ nígbà tí ẹ bá wà nínú aṣọ hurumi (hajj tàbí ‘umrah)1. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ọ́mọ̀ pa á nínú yín, ẹ̀san rẹ̀ ni (pé ó máa pa) irú ohun tí ó pa nínú ẹran ọ̀sìn. Àwọn onídéédé méjì nínú yín l’ó sì máa ṣe ìdájọ́ (òṣùwọ̀n) rẹ̀ (fún un. Ó máa jẹ́) ẹran ọrẹ tí ó máa mú dé Kaaba. Tàbí kí ó fi bíbọ́ àwọn tálíkà ṣe ìtánràn. Tàbí kí ó fi ààwẹ̀ dípò ìyẹn, nítorí kí ó lè tọ́ bí ọ̀ràn rẹ̀ ṣe lágbára tó wò. Allāhu ti mójú kúrò níbi ohun tó ré kọjá. Ẹnikẹ́ni tí ó bá tún padà (mọ̀ọ́mọ̀ dọdẹ nínú aṣọ húrùmí tàbí nínú húrùmí), Allāhu yóò gbẹ̀san lára rẹ̀ rẹ̀. Allāhu sì ni Alágbára, Olùgbẹ̀san.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Tàbí tí ẹ bá wà lórí ilẹ̀ ọ̀wọ̀.