Suratu Al-Ma'idah, aaya 31

5:31

فَبَعَثَ ٱللَّهُ غُرَابٗا يَبۡحَثُ فِي ٱلۡأَرۡضِ لِيُرِيَهُۥ كَيۡفَ يُوَٰرِي سَوۡءَةَ أَخِيهِۚ قَالَ يَٰوَيۡلَتَىٰٓ أَعَجَزۡتُ أَنۡ أَكُونَ مِثۡلَ هَٰذَا ٱلۡغُرَابِ فَأُوَٰرِيَ سَوۡءَةَ أَخِيۖ فَأَصۡبَحَ مِنَ ٱلنَّٰدِمِينَ ٣١

Faba'athallāhu ghurāban yabhathu fil-ardi liyuriyahū kayfa yuwārī saw'ata akhīhi qāla yāwaylatā a'ajaztu an akūna mithla hādhal-ghurābi fa uwāriya saw'ata akhī fa asbaha minan-nādimīn

Allāhu sì gbé ẹyẹ kannakánná kan dìde, tí ó ń fi ẹsẹ̀ walẹ̀ nítorí kí ó lè fi bí ó ṣe máa bo òkú1 arákùnrin rẹ̀ mọ́ inú ilẹ̀ hàn án. Ó wí pé: “Tèmí bá mi o! Ṣé mo kágara ni láti dà bí irú ẹyẹ kannakánná yìí, kí èmi náà sì lè bo òkú arákùnrin mi mọ́lẹ̀?” Ó sì di ara àwọn alábàámọ̀.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 “sao’ah” túmọ̀ sí ìhòhò, ohun tí ẹ̀dá kò fẹ́ fojú ara rẹ̀ rí. Òkú ti di sao’ah nítorí pé, kò sí ẹni tí ó fẹ́ fojú ara rẹ̀ rí òkú.