وَٱصۡبِرۡ نَفۡسَكَ مَعَ ٱلَّذِينَ يَدۡعُونَ رَبَّهُم بِٱلۡغَدَوٰةِ وَٱلۡعَشِيِّ يُرِيدُونَ وَجۡهَهُۥۖ وَلَا تَعۡدُ عَيۡنَاكَ عَنۡهُمۡ تُرِيدُ زِينَةَ ٱلۡحَيَوٰةِ ٱلدُّنۡيَاۖ وَلَا تُطِعۡ مَنۡ أَغۡفَلۡنَا قَلۡبَهُۥ عَن ذِكۡرِنَا وَٱتَّبَعَ هَوَىٰهُ وَكَانَ أَمۡرُهُۥ فُرُطٗا ٢٨
Wasbir nafsaka ma'al-ladhīna yad'ūna rabbahum bil-ghadawāti wal-'ashiyyi yurīdūna wajhahū walā ta'du 'aynāka 'anhum turīdu zīnatal-hayawātid-dunyā walā tuti' man aghfalnā qalbahū 'an dhikrinā wattaba'a hawāhu wakāna amruhū furutā
Ṣe sùúrù fún ẹ̀mí rẹ láti wà pẹ̀lú àwọn tó ń pe Olúwa wọn ní òwúrọ̀ àti ní àṣálẹ́, tí wọ́n ń wá Ojú rere Rẹ̀. Má ṣe fojú pa wọ́n rẹ́ láti wá ọ̀ṣọ́ ìṣẹ̀mí ayé (yìí). Má sì ṣe tẹ̀lé ẹni tí A mú ọkàn rẹ̀ gbàgbé ìrántí Wa. Ó tẹ̀lé ìfẹ́-inú rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ àṣejù.1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Àwọn onisūfi lérò pé āyah yìí gbè fún àwọn. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al- ’An‘ām; 6:52 fún àgbọ́yé āyah yìí.