Suratu Al-Jinn, aaya 18

72:18

وَأَنَّ ٱلۡمَسَٰجِدَ لِلَّهِ فَلَا تَدۡعُواْ مَعَ ٱللَّهِ أَحَدٗا ١٨

Wa annal-masājida lillāhi falā tad'ū ma'allāhi ahadā

Dájúdájú àwọn mọ́sálásí ń jẹ́ ti Allāhu.1 Nítorí náà, ẹ kò gbọ́dọ̀ pe ẹnì kan pẹ̀lú Allāhu.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Nínú ìtúmọ̀ mìíràn fún āyah yìí kalmọh “mọsājid” dúró fún àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀. Àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ ni iwájú orí àti góńgórí imú, àtẹ́lẹwọ́ méjéèjì, orúnkún méjéèjì àti orí ọmọníkasẹ̀ méjéèjì. Èèwọ̀ ni fún ẹ̀dá lati fi ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara ìforíkanlẹ̀ wọ̀nyí jọ́sìn tàbí kí ẹnikẹ́ni.