Suratu Al-Imran, aaya 184

3:184

فَإِن كَذَّبُوكَ فَقَدۡ كُذِّبَ رُسُلٞ مِّن قَبۡلِكَ جَآءُو بِٱلۡبَيِّنَٰتِ وَٱلزُّبُرِ وَٱلۡكِتَٰبِ ٱلۡمُنِيرِ ١٨٤

Fa in kaddhabūka faqad kuddhiba rusulum min qablika jā'ū bil-bayyināti waz-zuburi wal-kitābil-munīr

Tí wọ́n bá pè ọ́ ní òpùrọ́, wọ́n kúkú ti pe àwọn Òjíṣẹ́ tó ṣíwájú rẹ ní òpùrọ́. Wọ́n wá pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tó yanjú, ìpín-ìpín Tírà àti Tírà tó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Àpẹ̀ẹrẹ fún ìpín-ìpín Tírà ni suhf ’Ibrọ̄hīm àti suhf Mūsā. Àpẹ̀ẹrẹ fún Tírà tó ń tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ni az-Zabūr, at-Taorāh, al-’Injīl àti al-Ƙur’ān Alápọ̀n-ọ́nlé.