Suratu Al-Hajj, aaya 67

22:67

لِّكُلِّ أُمَّةٖ جَعَلۡنَا مَنسَكًا هُمۡ نَاسِكُوهُۖ فَلَا يُنَٰزِعُنَّكَ فِي ٱلۡأَمۡرِۚ وَٱدۡعُ إِلَىٰ رَبِّكَۖ إِنَّكَ لَعَلَىٰ هُدٗى مُّسۡتَقِيمٖ ٦٧

Llikulli ummatin ja'alnā mansakan hum nāsikūhu falā yunāzi'unnaka fil-amri wad'u ilā rabbika innaka la'alā hudam mustaqīm

Ìjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò. Nítorí náà, kí wọ́n má ṣe jà ọ́ níyàn nípa ọ̀rọ̀ náà. Kí o sì pèpè sọ́dọ̀ Olúwa rẹ. Dájúdájú o kúkú wà lójú ọ̀nà tààrà. 1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Gbólóhùn yìí “Ìjọ kọ̀ọ̀kan l’A fún ní ìlànà tí wọ́n máa lò.” Ìyẹn nínú ’Islām tí Allāhu fi rán Òjíṣẹ́ wọn sí wọn nítorí pé, ’Islām ni ẹ̀sìn gbogbo àwọn Ànábì àti àwọn Òjísẹ́ Olọ́hun, àmọ́ ìlànà ìjọ́sìn kan láààrin ìjọ Òjíṣẹ́ kan sí òmíràn lè yàtọ̀.