وَٱلَّذِينَ لَا يَشۡهَدُونَ ٱلزُّورَ وَإِذَا مَرُّواْ بِٱللَّغۡوِ مَرُّواْ كِرَامٗا ٧٢
Walladhīna lā yashhadūnaz-zūra wa idhā marrū bil-laghwi marrū kirāmā
(Àwọn ni) àwọn tí kò jẹ́rìí èké. Tí wọ́n bá sì kọjá níbi ìbàjẹ́, wọ́n á kọjá pẹ̀lú àpọ́nlé.1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìyẹn ni pé, àwọn ẹrúsìn Allāhu ń pọ́nra wọn lé nípa àìjókòó pọ̀ pẹ̀lú àwọn onísọkúsọ. Wọ́n sì ń pọ́nra wọn lé nípa yíyẹra fún ìjókòó tí àwọn aláìmọ̀kan bá ti ń ṣe ìbàjẹ̀ nínú rẹ̀.