Suratu Al-Furqan, aaya 54

25:54

وَهُوَ ٱلَّذِي خَلَقَ مِنَ ٱلۡمَآءِ بَشَرٗا فَجَعَلَهُۥ نَسَبٗا وَصِهۡرٗاۗ وَكَانَ رَبُّكَ قَدِيرٗا ٥٤

Wahuwal-ladhī khalaqa minal-mā'i basharan faja'alahū nasaban wasihran wakāna rabbuka qadīrā

Òun ni Ẹni tí Ó ṣẹ̀dá abara láti inú omi. Ó ṣe ìbátan ẹbí àti ìbátan àna fún un, Olúwa rẹ sì ń jẹ́ Alágbára.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìṣẹ̀dá ènìyàn wáyé nípasẹ̀ oríṣi ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìkíní; nípasẹ̀ erùpẹ̀. Ìkejì; nípasẹ̀ ẹfọ́nhà. Ìkẹta; nípasẹ̀ omi àtọ̀. Ìkẹrin; nípasẹ̀ atẹ́gùn ẹ̀mí àti gbólóhùn “kunfayakūn” Rẹ̀.