Suratu Al-Baqarah, aaya 53

2:53

وَإِذۡ ءَاتَيۡنَا مُوسَى ٱلۡكِتَٰبَ وَٱلۡفُرۡقَانَ لَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ ٥٣

Wa idh ātaynā mūsal-kitāba wal-furqāna la'allakum tahtadūn

(Ẹ rántí) nígbà tí A fún (Ànábì) Mūsā ní Tírà àti ọ̀rọ̀-ìpínyà nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ọmọ ‘Abbās - kí Allāhu yọ́nú sí àwọn méjèèjì - sọ pé, “Furƙọ̄n ni orúkọ fún àpapọ̀ gbogbo tírà Zabūr, Taorāt, ’Injīl àti Ƙur’ān. (Tọbariy) Ìdí sì nìyí tí al-Furƙọ̄n fi jẹ́ orúkọ mìíràn fún al-Ƙur’ān.