وَإِذۡ فَرَقۡنَا بِكُمُ ٱلۡبَحۡرَ فَأَنجَيۡنَٰكُمۡ وَأَغۡرَقۡنَآ ءَالَ فِرۡعَوۡنَ وَأَنتُمۡ تَنظُرُونَ ٥٠
Wa idh faraqnā bikumul-bahra fa anjaynākum wa aghraqnā āla fir'awna wa antum tanzurūn
(Ẹ rántí) nígbà tí A pín agbami òkun sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún yín,1 A sì gbà yín là. A tẹ àwọn ènìyàn Fir‘aon rì. Ẹ̀yin náà sì ń wò (wọ́n nínú agbami odò).
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Àwọn kan nínú àwọn onímọ̀ nípa Tafsīr sọ pé, “Agbami òkun pín sí méjì fún àwọn ọmọ Isrọ̄’īl, ojú-ọ̀nà ẹyọ kan sì là fún gbogbo wọn.” Àmọ́ ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn onímọ̀ nípa Tafsīr sọ pé, “Agbami òkun pín sí méjìlá fún wọn tí ìdìlé kọ̀ọ̀kan sì tọ ojú-ọ̀nà kọ̀ọ̀kan nítorí pé, ìdílé méjìlá ni ìran ọmọ Isrọ̄’īl.”