قُلۡنَا ٱهۡبِطُواْ مِنۡهَا جَمِيعٗاۖ فَإِمَّا يَأۡتِيَنَّكُم مِّنِّي هُدٗى فَمَن تَبِعَ هُدَايَ فَلَا خَوۡفٌ عَلَيۡهِمۡ وَلَا هُمۡ يَحۡزَنُونَ ٣٨
Qulnahbitū minhā jamī'an fa immā ya'tiyannakum minnī hudan faman tabi'a hudāya falā khawfun 'alayhim walā hum yahzanūn
A sọ pé1: “Gbogbo yín, ẹ sọ̀kalẹ̀ kúrò nínú rẹ̀. Nígbà tí ìmọ̀nà bá dé ba yín láti ọ̀dọ̀ Mi, ẹni tí ó bá tẹ̀lé ìmọ̀nà Mi, ìpáyà kò níí sí fún wọn. Wọn kò sì níí banújẹ́.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Kíyè sí i, nígbàkígbà tí Allāhu - subhānahu wa ta‘ālā - bá lo ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ “ọ̀pọ̀” dípò “ẹyọ” fún ara Rẹ̀, kò túmọ̀ sí pé “Ọlọ́hun Òdodo” pọ̀ ní òǹkà. Ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ ọ̀pọ̀ lè dúró fún ọ̀pọ̀ ní òǹkà tàbí àpọ́nlé.