۞ وَٱلۡوَٰلِدَٰتُ يُرۡضِعۡنَ أَوۡلَٰدَهُنَّ حَوۡلَيۡنِ كَامِلَيۡنِۖ لِمَنۡ أَرَادَ أَن يُتِمَّ ٱلرَّضَاعَةَۚ وَعَلَى ٱلۡمَوۡلُودِ لَهُۥ رِزۡقُهُنَّ وَكِسۡوَتُهُنَّ بِٱلۡمَعۡرُوفِۚ لَا تُكَلَّفُ نَفۡسٌ إِلَّا وُسۡعَهَاۚ لَا تُضَآرَّ وَٰلِدَةُۢ بِوَلَدِهَا وَلَا مَوۡلُودٞ لَّهُۥ بِوَلَدِهِۦۚ وَعَلَى ٱلۡوَارِثِ مِثۡلُ ذَٰلِكَۗ فَإِنۡ أَرَادَا فِصَالًا عَن تَرَاضٖ مِّنۡهُمَا وَتَشَاوُرٖ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡهِمَاۗ وَإِنۡ أَرَدتُّمۡ أَن تَسۡتَرۡضِعُوٓاْ أَوۡلَٰدَكُمۡ فَلَا جُنَاحَ عَلَيۡكُمۡ إِذَا سَلَّمۡتُم مَّآ ءَاتَيۡتُم بِٱلۡمَعۡرُوفِۗ وَٱتَّقُواْ ٱللَّهَ وَٱعۡلَمُوٓاْ أَنَّ ٱللَّهَ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرٞ ٢٣٣
Wal-wālidātu yurdi'na awlādahunna hawlayni kāmilayni liman arāda an yutimmar-radā'ata wa'alal-mawlūdi lahū rizquhunna wakiswatuhunna bil-ma'rūfi lā tukallafu nafsun illā wus'ahā lā tudārra wālidatu biwaladihā walā mawlūdul lahū biwaladihī wa'alal-wārithi mithlu dhālika fa in arādā fisālan 'an tarādim minhumā watashāwurin falā junāha 'alayhimā wa in arattum an tastardi'ū awlādakum falā junāha 'alaykum idhā sallamtum mā ātaytum bil-ma'rūfi wattaqullāha wa'lamū annallāha bimā ta'malūna basīr
Àwọn abiyamọ yóò máa fún àwọn ọmọ wọn ní ọyàn mu fún ọdún méjì gbáko, fún ẹni tí ó bá fẹ́ parí (àsìkò) ìfọ́mọlọ́yàn. Ojúṣe ni fún ẹni tí wọ́n bímọ fún láti máa ṣe (ètò) ìjẹ-ìmu wọn àti aṣọ wọn ní ọ̀nà tó dára. Wọn kò làbọ ẹ̀mí kan lọ́rùn àfi ìwọ̀n agbára rẹ̀. Wọn kò níí kó ìnira bá abiyamọ nítorí ọmọ rẹ̀. Wọn kò sì níí kó ìnira bá ẹni tí wọ́n bímọ fún nítorí ọmọ rẹ̀. Irú (ojúṣe) yẹn tún ń bẹ fún olùjogún.1 Tí àwọn méjèèjì bá sì fẹ́ gba ọyàn l’ẹ́nu ọmọ pẹ̀lú ìpanupọ̀ àti àṣàrò àwọn méjèèjì, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn méjèèjì. Tí ẹ bá sì fẹ́ gba ẹni tí ó máa fún àwọn ọmọ yín lọ́yàn mu, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ fún yín, tí ẹ bá ti fún wọn ní ohun tí ẹ fẹ́ fún wọn (ní owó-ọ̀yà) ní ọ̀nà tó dára. Ẹ bẹ̀rù Allāhu. Kí ẹ sì mọ̀ pé dájúdájú Allāhu ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 Ìyẹn ni pé, bí àpẹ̀ẹrẹ, kí bàbá kú níkété tí ìyàwó rẹ̀ bímọ tán, kò sì sí ogún kan dàbí alárà nílẹ̀ tí ó fi sílẹ̀ fún ọmọ rẹ̀, àmọ́ ọmọ yìí ní àwọn ẹ̀gbọ́n níwájú àti bàbáabàbá ní àwọn tó jẹ́ pé, wọ́n wà nínú àwọn tí ó lè jogún ọmọdé yìí bí ó bá jẹ́ pé, ó kú ṣíwájú wọn, tí ó sì fi ogún sílẹ̀. Nítorí náà, àwọn náà ni wọ́n máa dìjọ máa dá owó ìfọ́mọlọ́yàn fún obìnrin tí wọ́n gbà fún iṣẹ́ ìfọ́mọlọ́yàn lórí òdiwọ̀n ìpín ogún tí ó lè kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn.