Suratu Al-Baqarah, aaya 210

2:210

هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّآ أَن يَأۡتِيَهُمُ ٱللَّهُ فِي ظُلَلٖ مِّنَ ٱلۡغَمَامِ وَٱلۡمَلَٰٓئِكَةُ وَقُضِيَ ٱلۡأَمۡرُۚ وَإِلَى ٱللَّهِ تُرۡجَعُ ٱلۡأُمُورُ ٢١٠

Hal yanzurūna illā an ya'tiyahumullāhu fī zulalim minal-ghamāmi wal-malā'ikatu waqudiyal-amru wa ilallāhi turja'ul-umūr

Ṣé wọ́n ń retí kiní kan bí kò ṣe pé kí Allāhu wá bá wọn nínú ibòji ẹ̀ṣújò funfun,1 àwọn mọlāika náà (sì máa wá, nígbà náà), A ó sì yanjú ọ̀rọ̀ (ìṣírò iṣẹ́ ẹ̀dá)! Ọ̀dọ̀ Allāhu sì ni wọ́n máa ṣẹ́rí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀dá padà sí.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn máa ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Àjíǹde tí gbogbo sánmọ̀ máa fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ẹ wo sūrah al-Furƙọ̄n; 25:25, sūrah al-’Infitọ̄r; 82:1-2 àti sūrah al-’Inṣiƙọ̄ƙ; 84:1-2.