Suratu Al-Baqarah, aaya 164

2:164

إِنَّ فِي خَلۡقِ ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱخۡتِلَٰفِ ٱلَّيۡلِ وَٱلنَّهَارِ وَٱلۡفُلۡكِ ٱلَّتِي تَجۡرِي فِي ٱلۡبَحۡرِ بِمَا يَنفَعُ ٱلنَّاسَ وَمَآ أَنزَلَ ٱللَّهُ مِنَ ٱلسَّمَآءِ مِن مَّآءٖ فَأَحۡيَا بِهِ ٱلۡأَرۡضَ بَعۡدَ مَوۡتِهَا وَبَثَّ فِيهَا مِن كُلِّ دَآبَّةٖ وَتَصۡرِيفِ ٱلرِّيَٰحِ وَٱلسَّحَابِ ٱلۡمُسَخَّرِ بَيۡنَ ٱلسَّمَآءِ وَٱلۡأَرۡضِ لَأٓيَٰتٖ لِّقَوۡمٖ يَعۡقِلُونَ ١٦٤

Inna fī khalqis-samāwāti wal-ardi wakhtilāfil-layli wan-nahāri wal-fulkil-latī tajrī fil-bahri bimā yanfa'un-nāsa wamā anzalallāhu minas-samā'i mim mā'in fa ahyā bihil-arda ba'da mawtihā wabattha fīhā min kulli dābbatin watasrīfir-riyāhi was-sahābil-musakkhari baynas-samā'i wal-ardi la'āyātil liqawmin ya'qilūn

Dájúdájú àwọn àmì wà nínú ìṣẹ̀dá àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀, ìtẹ̀léǹtẹ̀lé òru àti ọ̀sán, àti àwọn ọkọ̀ ojú-omi tó ń rìn lórí omi pẹ̀lú (ríru) ohun tó ń ṣe àwọn ènìyàn ní àǹfààní, àti ohun tí Allāhu ń sọ̀kalẹ̀ ní omi láti sánmọ̀, tí Ó sì ń fi sọ ilẹ̀ di ààyè lẹ́yìn tí ó ti kú, àti (bí) Ó ṣe fọ́n gbogbo ẹranko ká sí orí ilẹ̀, àti ìyípadà atẹ́gùn1 àti ẹ̀ṣújò tí A tẹ̀ba láààrin sánmọ̀ àti ilẹ̀; (àmì wà nínú wọn) fún ìjọ tó ń ṣe làákàyè.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyípadà atẹ́gùn túmọ̀ sí oríṣi atẹ́gùn àti àwọn ibùfẹ́ atẹ́gùn.