Suratu Al-Baqarah, aaya 154

2:154

وَلَا تَقُولُواْ لِمَن يُقۡتَلُ فِي سَبِيلِ ٱللَّهِ أَمۡوَٰتُۢۚ بَلۡ أَحۡيَآءٞ وَلَٰكِن لَّا تَشۡعُرُونَ ١٥٤

Walā taqūlū liman yuqtalu fī sabīlillāhi amwātu bal ahyā'un walākil lā tash'urūn

Ẹ má ṣe pe àwọn tí wọ́n ń pa sí ojú-ọ̀nà Allāhu (ojú-ogun ẹ̀sìn) ní òkú (ìyà), àmọ́ alààyè (ẹni ìkẹ́) ni wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fura.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, ikú láádá ni wọ́n kú, ẹni ìkẹ́ sì ni wọ́n.