Suratu Al-Baqarah, aaya 150

2:150

وَمِنۡ حَيۡثُ خَرَجۡتَ فَوَلِّ وَجۡهَكَ شَطۡرَ ٱلۡمَسۡجِدِ ٱلۡحَرَامِۚ وَحَيۡثُ مَا كُنتُمۡ فَوَلُّواْ وُجُوهَكُمۡ شَطۡرَهُۥ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَيۡكُمۡ حُجَّةٌ إِلَّا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡهُمۡ فَلَا تَخۡشَوۡهُمۡ وَٱخۡشَوۡنِي وَلِأُتِمَّ نِعۡمَتِي عَلَيۡكُمۡ وَلَعَلَّكُمۡ تَهۡتَدُونَ ١٥٠

Wamin haythu kharajta fawalli wajhaka shatral-masjidil-harāmi wahaythu mā kuntum fawallū wujūhakum shatrahū li allā yakūna lin-nāsi 'alaykum hujjatun illal-ladhīna zalamū minhum falā takhshawhum wakhshawnī wali'utimma ni'matī 'alaykum wala'allakum tahtadūn

Ibikíbi tí o bá jáde lọ, kọjú rẹ sí agbègbè Mọ́sálásí Haram. Àti pé ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ kọjú yín sí agbègbè rẹ̀,1 nítorí kí àwọn ènìyàn má baà ní àwíjàre lórí yín, àyàfi àwọn tí wọ́n ṣàbòsí nínú wọn (tí wọn kò yé jà yín níyàn). Nítorí náà, ẹ má ṣe páyà wọn. Ẹ páyà Mi, nítorí kí N̄g lè pé ìdẹ̀ra Mi fún yín àti nítorí kí ẹ lè mọ̀nà.

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Àwọn āyah wọ̀nyí 144, 149 àti 150 ń pa wá láṣẹ láti dojúkọ agbègbè Kaabah lórí ìrun, ìyẹn sì ni agbègbè tí Kaabah wà sí ìlú ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí mọ́sálásí ẹnì kọ̀ọ̀kan. Ohun tó bí “agbègbè” dípò “ọ̀gangan” Kaabah ni pé, kò lè rọrùn rárá fún àwọn tí kò sí nínú mọ́sálásí Haram Mọkkah láti dojúkọ ọ̀gangan Kaabah láti àyè mìíràn lórí ìrun wọn.