Suratu Al-A'raf, aaya 53

7:53

هَلۡ يَنظُرُونَ إِلَّا تَأۡوِيلَهُۥۚ يَوۡمَ يَأۡتِي تَأۡوِيلُهُۥ يَقُولُ ٱلَّذِينَ نَسُوهُ مِن قَبۡلُ قَدۡ جَآءَتۡ رُسُلُ رَبِّنَا بِٱلۡحَقِّ فَهَل لَّنَا مِن شُفَعَآءَ فَيَشۡفَعُواْ لَنَآ أَوۡ نُرَدُّ فَنَعۡمَلَ غَيۡرَ ٱلَّذِي كُنَّا نَعۡمَلُۚ قَدۡ خَسِرُوٓاْ أَنفُسَهُمۡ وَضَلَّ عَنۡهُم مَّا كَانُواْ يَفۡتَرُونَ ٥٣

Hal yanzurūna illā ta'wīlahū yawma ya'tī ta'wīluhū yaqūlul-ladhīna nasūhu min qablu qad jā'at rusulu rabbinā bil-haqqi fahal lanā min shufa'ā'a fayashfa'ū lanā aw nuraddu fana'mala ghayral-ladhī kunnā na'malu qad khasirū anfusahum wadalla 'anhum mā kānū yaftarūn

Kí ni wọ́n ń retí bí kò ṣe ẹ̀san Rẹ̀?1 Lọ́jọ́ tí ẹ̀san Rẹ̀ bá dé, àwọn tó gbàgbé rẹ̀ ṣíwájú yóò wí pé: “Dájúdájú àwọn Òjíṣẹ́ Olúwa wa ti mú òdodo wá. Nítorí náà, ǹjẹ́ a lè rí àwọn olùṣìpẹ̀, kí wọ́n wá ṣìpẹ̀ fún wa tàbí kí wọ́n dá wa padà sílé ayé, kí á lè ṣe iṣẹ́ mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí a máa ń ṣe?” Dájúdájú wọ́n ti ṣe ẹ̀mí wọn lófò. Ohun tí wọ́n sì ń dá ní àdápa irọ́ sì di òfo mọ́ wọn lọ́wọ́.2

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ìyẹn ni pé, ohun tí ó máa kángun ọ̀rọ̀ àwọn aláìgbàgbọ́ nínú ìyà ní Ọjọ́ Ẹ̀san. [2] Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ sūrah al-’Ani‘ām; 6:24.