Suratu Al-'Ankabut, aaya 46

29:46

۞ وَلَا تُجَٰدِلُوٓاْ أَهۡلَ ٱلۡكِتَٰبِ إِلَّا بِٱلَّتِي هِيَ أَحۡسَنُ إِلَّا ٱلَّذِينَ ظَلَمُواْ مِنۡهُمۡۖ وَقُولُوٓاْ ءَامَنَّا بِٱلَّذِيٓ أُنزِلَ إِلَيۡنَا وَأُنزِلَ إِلَيۡكُمۡ وَإِلَٰهُنَا وَإِلَٰهُكُمۡ وَٰحِدٞ وَنَحۡنُ لَهُۥ مُسۡلِمُونَ ٤٦

Walā tujādilū ahlal-kitābi illā billatī hiya ahsanu illal-ladhīna zalamū minhum waqūlū āmannā billadhī unzila ilaynā wa unzila ilaykum wa ilāhunā wa ilāhukum wāhidun wanahnu lahū muslimūn

Ẹ má ṣe bá àwọn onítírà ṣàríyàn jiyàn àfi ní ọ̀nà tó dára jùlọ (èyí ni lílo al-Ƙur’ān àti hadīth. Ẹ má sì ṣe jà wọ́n lógun) àfi àwọn tó bá ṣàbòsí nínú wọn.1 Kí ẹ sì sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún àwa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún ẹ̀yin. Ọlọ́hun wa àti Ọlọ́hun yín, (Allāhu) Ọ̀kan ṣoṣo ni. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀-sílẹ̀) fún Un.”

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé alábòsí wulẹ̀ ni gbogbo àwọn onítírà, àbòsí mìíràn ni Allāhu ń tọ́ka sí lára wọn nínú āyah yìí.