فَلَمَّا رَءَا ٱلشَّمۡسَ بَازِغَةٗ قَالَ هَٰذَا رَبِّي هَٰذَآ أَكۡبَرُۖ فَلَمَّآ أَفَلَتۡ قَالَ يَٰقَوۡمِ إِنِّي بَرِيٓءٞ مِّمَّا تُشۡرِكُونَ ٧٨
Falammā ra'ash-shamsa bāzighatan qāla hādhā rabbī hādhā akbaru falammā afalat qāla yāqawmi innī barī'um mimmā tushrikūn
Nígbà tí ó rí òòrùn tó yọ, ó sọ pé: “Èyí ni olúwa mi; èyí tóbi jùlọ.” Nígbà tó wọ̀, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú èmi yọwọ́ yọsẹ̀ nínú ohun tí ẹ ń fi ṣẹbọ (sí Allāhu).1
Àlàyé ìsàlẹ̀
1 “Ànábì ’Ibrọ̄hīm - kí ọlà Allāhu máa bá a - mú ọ̀rọ̀ náà wá lójú pọ̀n-nà ìgbémọ́ra àti ìjẹ́nilẹ́gọ̀ọ́ láti sọ àròjàre ìjọ rẹ̀ di àròjẹ̀bi wọn, kì í ṣe lójú pọ̀n-nà ìṣeyèméjì nípa Allāhu - subhānahu wa ta'ālā -.