Suratu Al-Ahzab, aaya 9

33:9

يَٰٓأَيُّهَا ٱلَّذِينَ ءَامَنُواْ ٱذۡكُرُواْ نِعۡمَةَ ٱللَّهِ عَلَيۡكُمۡ إِذۡ جَآءَتۡكُمۡ جُنُودٞ فَأَرۡسَلۡنَا عَلَيۡهِمۡ رِيحٗا وَجُنُودٗا لَّمۡ تَرَوۡهَاۚ وَكَانَ ٱللَّهُ بِمَا تَعۡمَلُونَ بَصِيرًا ٩

Yā'ayyuhal-ladhīna āmanudhkurū ni'matallāhi 'alaykum idh jā'atkum junūdun fa arsalnā 'alayhim rīhan wajunūdal lam tarawhā wakānallāhu bimā ta'malūna basīrā

Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ rántí ìdẹ̀ra Allāhu lórí yín, nígbà tí àwọn ọmọ ogun (oníjọ) dé ba yín. A sì rán atẹ́gùn àti àwọn ọmọ ogun tí ẹ kò fójú rí sí wọn. Allāhu sì ni Olùríran nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Ọmọ ogun oníjọ ni àwọn ọmọ ogun ìjọ mẹ́ta kan tó para pọ̀ lórí ìjọ ọmọ ogun Ànábì - kí ìkẹ́ àti ọlà Allāhu máa bá a - : ìjọ ọmọ ogun Ƙuraeṣi, ìjọ ọmọ ogun Gatfān àti ìjọ ọmọ ogun Yẹhudi tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ Nadīr.