Suratu Al-Ahzab, aaya 72

33:72

إِنَّا عَرَضۡنَا ٱلۡأَمَانَةَ عَلَى ٱلسَّمَٰوَٰتِ وَٱلۡأَرۡضِ وَٱلۡجِبَالِ فَأَبَيۡنَ أَن يَحۡمِلۡنَهَا وَأَشۡفَقۡنَ مِنۡهَا وَحَمَلَهَا ٱلۡإِنسَٰنُۖ إِنَّهُۥ كَانَ ظَلُومٗا جَهُولٗا ٧٢

Innā 'aradnal-amānata 'alas-samāwāti wal-ardi wal-jibāli fa abayna an yahmilnahā wa ashfaqna minhā wahamalahal-insānu innahū kāna zalūman jahūlā

Dájúdájú Àwa fi àgbàfipamọ́ (iṣẹ́ ẹ̀sìn àṣegbaláádá) lọ àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ àti àpáta. Wọ́n kọ̀ láti gbé e; wọ́n páyà rẹ̀. Ènìyàn sì gbé e. Dájúdájú (ènìyàn) jẹ́ alábòsí, aláìmọ̀kan.1

Àlàyé ìsàlẹ̀

1 Àgbàfipamọ́ ni ìtúmọ̀ “ ’amọ̄nah”. Èyí sì túmọ̀ sí ohun tí wọ́n gbé lé wa lọ́wọ́ fún ṣíṣọ́ àti àmójútó. Ohun tí Allāhu - tó ga jùlọ - gbélé wa lọ́wọ́ tí a óò máa ṣọ́, tí a óò máa ṣe àmójútó rẹ̀ títí di ọjọ́ ikú ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni ẹ̀sìn Rẹ̀, ’Islām. Allāhu sì gbé ẹ̀sìn náà kalẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀san.